AJOSE ONIGBAGBO
Jesu Kristi gbadura fun awon omo ehin re ki won le gba emi ife, ki won le wa ni isokan. Jesu wipe ‘Emi ko si si ni aye mo, awon wonyi si nbe ni aye, emi si nbo wa sodo re baba mimo, pa awon ti o ti fifun mi mo ni oruko re, ki won ki o le je okan ani gege bi awa.
(Johanu 17:11)
EKO
Awon onigbagbo ninu Jesu Kristi ni lati ni ajose papo ninu ife, Jesu fi eyi han nigba ti o gbadura ki Olorun so won po ni ife (Johanu 17:11) gbogbo kristieni ni lati gbiyanju ki ife ki o wa ninu agbo Kristi. Ki olukuluku ijo paa ti si apa kan, iwa igberaga, eleya meya, ki won wa sise papo fun itesiwaju ipologo ihinrere. Orisirisi ijo, asa awon ebun, o le maa toka si orisirisi eya ara ti iwe mimo ntoka si ninu Bibeli (Korinti Kini 12:12-26). Ohunkohun ti o le je iyato wa, gbogbo kristieni je arak an labe agborun Jesu Kristi, nitorina a ni lati rin ki a si sise papo. A nilati ma wa Alafia ara wa, ki a si maa gbadura fun ara wa, ara Kristi ni lati wa ni isokan lati rii wipe wiwaasu ihinrere Jesu Kristi lo kakiri agbaye. Ijo nilati se ipolongo iwa mimo ati isododo ni osuwon ti Olorun.
ADURA
Olorun olufe jowo so eya ara kristieni papo si isokan, je ki awon adari ijo ati awon omo ijo wa ni iteriba fun o. je ki ijo kokan re asa won sile fun osuwon Bibeli, je ki gbogbo ijo ati awon ara fowo sowo po, ki ale polongo otito ni ile wa. Je ki ijo kaa si Pataki jule kikede ihinrere, ki won fi gbogbo ara see, ki awon alaigbagbo kakiri agbaye le ni anfani lati di eni igbala. Ma se je ki awon eniyan ja o kule sugbon je ki nfi Alafia ati igbagbo sin o, ki emi le di eni ibukun ni aye ati ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
