EERE WA FUN ENIYAN BUBURU
Dafidi oba se ijafara pelu Olorun, o si wonu iyoni ni kiakia. Nigba ti o ye ki o wa ni oju ogun fun idabobo orile ede re, o wa ni afin ti o nje igbadun, o si de pakute fun isubu re, ni aafin Dafidi ko lee se ikora eni nijanu mo, o da ese agbere si iyawo aladugbo re. O si pa oko obirin naa nireti lati bo ese re mole, iwa ese yi ta epo si aso funfun Dafidi, eyi bi Olorun ninu o si seto ijiya fun.
Iwa ese Dafidi ti o ba eri rere re je ni a ko sinu Bibeli ‘O si se leyin igba ti odun yipo, ni akoko igba ti awon oba maa njade ogun, Dafidi si ran Joabu ati awon iranse re pelu re ati gbogbo Isreali, won si pa awon omo Amoni, won si do ti Raba. Dafidi si jokoo ni Jerusalemu, o si se ni igba asale kan, Dafidi si dide ni ibusun re, o si nrin lori orule ile oba, lati ori orule naa ni o si ri obirin kan ti o nweara re, obirin naa si se arewa jojo lati wo. Dafidi si ranse, o si beere obirin naa, enikan siwi pe, eyi ko ni Batseba, omobirin Eliami, aya Uria ara Hiti. Dafidi si ran awon iranse, o si mu un, oun si wo inu ile too lo oun si ba dapo, nigba ti o si we ara re mo tan, o si pada lo si ile re. obirin naa si fera ku, o si ranse o si so fun Dafidi, o si wi pe emi fera ku. O si se ni owuro Dafidi si kowe si Joabu, o fi ran Uria o si ko sinu iwe pe, fi Uria siwaju ibi ti ogun gbe le, ki e si bo o sile, ki won le ko luu, ki o si ku.
(Samueli keji 11:1-5, 14-15)
Natani siwi fun Dafidi pe, iwo ni okunrin naa, bayii ni Oluwa Olorun Isreali wi, emi fi o joba lori Isreali, emi si gba o lowo Saulu. Emi si fi ile Oluwa re fun o ati awon obirin Oluwa re se aya re, emi si fi idile Isreali ati ti Juda fun o, iba tile se pe eyi nni kere ju, emi iba si fun o ni nnkan bayii bayii. Eese ti iwo fi kegan oro Oluwa, ti iwo fi se nnkan ti o buru ni oju re, ani ti iwo fi fi ida pa Uria ara Hiti, ati ti iwo fi mu obirin re lati fi se obirin re, o si fi ida awon omo Amoni paa. Nje nitori naa ida ki yoo kuro ni ile re titi lae, nitori pe iwo gan mi, iwo si mu aya Uria ara Hiti lati fi se aya re, bayii ni Oluwa wi, kiyesii emi o je ki ibi ki o dide si o lati inu ile re wa, emi o si gba awon obirin re loju re, emi o si fi won fun aladugbo re, oun o si ba awon obinrin re sun niwaju oorun yii, ati pe iwo see ni ikoko sugbon emi o se nnkan yii niwaju gbogbo Isreali ati niwaju oorun.
(Samueli keji 12:7-12)
EKO
Esan yi o de ba awon eniyan buburu bi o ti wu ki won sare to. Enikeni ti o ba se ibi ti o si lero lati mu je, onitohun nse awada ni. Olorun mo bi o se le mu awon eniyan buburu ki o si fi iya je won, ko si enikeni ti o le sapamo niwaju Oluwa, nitori ti o mo ohun gbogbo yi o si san esan ohun gbogbo, nitori naa, onise ibi oni ti o ni oro, o le je ere iwa ibi re ni ola. Gbogbo eniyan ni a penija ki a beru Oluwa, ki a si se ohun ti o tona ni abe iso oju re.
ADURA
Olorun olufe, jowo ko mi bi mo se le maa gbadura. Ran mi lowo lati le ma so edun okan mi ni igbakigba. Si je kin ni igbagbo pe o o dami lohun nigba ti mo ba gbadura si o. Jowo fun mi ni ore ofe lati le je anfani adura, ki o si dara fun mi ni gbogbo ojo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
