B’OWO FUN AWON ENI IFAMI ORORO YAN OLORUN
Paulu ati Barnaba fi oye ye awon eniyan ti o nfiyin fun won, ki won mase yin eniyan, bikose Olorun. Nigbati Paulu waasu ti o si se ise iyanu ni Listra gbogbo eniyan ro wipe Olorun ni, won si fe se irubo sii. Sugbon awon efangelisi meji yi kilo fun won ki won mase bee. Akosile wipe okunrin kan si jokoo ni Listra, eni ti ese re ko mokun, aro lati inu iyare wa, ti ko rin ri. Okunrun yi gbo bi Paulu ti nsoro, eni nigba ti o teju mo ti o sirii pe o ni igbagbo fun imularada. O wi fun ni ohun rara pe. Didi duro sansan ni ese re, o sinfo soke o si nrin. Nigba ti awon eniyan si ri ohun ti Paulu se, won gbe ohun wo soke ni ede Likaonia, wipe, awon orisa sokale to wa wa ni awo eniyan. Sugbon nigba ti awon Aposteli Barnaba ati Paulu gbo, won fa so won ya, won si sure wo inu awujo, won nke rara. Won sin wipe, ara, eese ti eyin fin se nnkan wonyi? Eniyan oniru iwa kan naa bi eyin ni awa pelu ti a nwaasu ihinrere fun yin, ki eyin ki o yipada kuro ninu ohun asan wonyi si Olorun alaaye, ti o da orun ati aye, ati okun, ati ohun gbogbo tin be ninu won. (Awon Aposteli 14:8-11, 14-15)
EKO
O ye ki a bowo fun awon iranse Olorun, sugbon ko ye ki a maa sin won. O ye ki a mo iyato laarin bibowo fun ati sisin. O se pataki ki a mo ojuse wa si Olorun ati awon iranse re lai koja ala won sira won. Olorun nikan lo to si lati maa sin, iranse Olorun lo ye ki a bowo fun. Olorun teti leko, o si kun fun ogo, ko si ni ba enikeni pin ninu ogo re. (Isaiah 42:8) Awon iranse Olorun ni agbara ti emi, won gba agbara lati waasu ihinrere ati ase lati dari okan awon eniyan si Olorun.
ADURA
Olorun Olufe je ki emi kiyesara, ki emi mase fi ogo ti o to si o fun eniyan eleran ara. Je kii emi maa fun o ni ogo ati ola ti o ye O ni gbogbo igba. Si fun mi ni ore ofe lati bowo fun awon iranse re, ki emi le ri ibukun re gba. Ranmi lowo lati le gbadura, ki emi si je oluralowo fun awon iranse re, ki o je okunfa lati sin o sii. Jowo bukun mi bi mo se pinu lati gboran si ofin re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
