ENIYAN OLOKAN EMI ISORE YIO GBADUN OLORUN
Nehemiah gbo nipa ipo ainifokanbale ti awon Israeli wa (awon eniyan re) inu re si baje. Ilu olokiki re (Jerusalem pelu) ati olugbe re wa ninu idamu. Irohin naa mu ki Nehimiah gbadura pelu awe si Olorun lati gbakoso. Bibeli wipe ni Hanani, okan ninu awon arakunrin mi, oun ati awon okurin kan lati Juda ti o sala, ti o ku ninu awon igbekun ati nipa Jerusalem. Won si wi fun mi pe, awon ijoku, ati a fi sile nibe ninu awon igbekun ni igberiko, nbe ninu wahala nla ati egan. Odi Jerusalem si wo lule, a si fi ilekun re jona. Osi se nigba ti mo gbo oro wonyi, mo jokoo, mo si sunkun, mo si sofo ni iye ojo, mo si gbaawe mo si gbadura niwaju Olorun orun. (Nehemiah 1:2-4). Olorun dahun ebe Nehemiah, o fun ni ore-ofe niwaju alaigbagbo/keferi oba, lati pada si ile, lati tun ilu re ko.
EKO
Olorun feran awon ti o nran eniyan lowo. Inu re maa ndun si eni ti o ba wa ohun rere fun elomiran. Jehofa yio bukun, yi o si b’ola fun irufe eni bee, oju ko ni tii. Gbogbo awon ti won ba ni inu didun lati ran eniyan lowo, oju won yio maa dan pelu ewa anfani iyanu. Won le ni akoko inilara die ninu aye, sugbon won yio bori. Jehofa yi o gbe awon olokan rere soke, ki won le tesiwaju ninu ise rere won. Eni ti o ba ni okan isore yi o je anfani Olorun ni aye yi ati eyi ti mbo wa. Awon iran won ti nbo yi o je ninu eso ise rere won. Ohun rere kan ko ni se awati ninu aye eni ti okan re ro mo Olorun, ti o si je asoju Jesu Kristi ninu aye awon eniyan. Olorun yi o b’ola fun won.
ADURA
Olorun olufe jowo fun mi ni okan ti o nran eniyan lowo. Je ki emi je idahun si aini awon eniyan. Fun mi ni ore-ofe lati lee ran opolopo eniyan lowo. Se mi ni eni ti un yonju isoro, ki emi mase je eni ti o nfa wahala. Se mini asoju re ni aye, ki oruko re di yiyin ni ile alaaye. (Dahun ebe adura mi, ki emi le ri idi lati maa sin o). Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
