ISIN OLORUN KEKEKE O LODI SI OLORUN
Oba kan ti a npe ni Jehu gbe igbese akoni lati ja fun awon omo Israeli ti o si te Olorunlorun. O gbe ese ibinu re sori iborisa, o si seto pipa gbogbo awon aborisa. Bibeli wipe o si se bi a si ti pari ati ru ebo sisun, ni Jehu wi fun awon oluso ati awon olori ogun pe, wole ki e si pa won e mase je ki enikan ki o jade, won si fi oju ida pa won, awon oluso ati awon olori-ogun si gbe won so si ode, won si wo inu odi ile Baali. Won si ko awon ere lati ile Baali jade, won si sun won. Won si wo eere Baali lule, won si wo ile Baali lule, won si see ni ile igbe titi di oniyi. (2 Awon Oba 10:25-27)
EKO
Olorun korira iborisa, o si ko aborisa. Olorun nikan lo to ki gbogbo eniyan maa sin. Ko si Olorun mira, ni ofurufu, ni ori ile tabi ninu omi ti o ye lati maa sin. Olorun ni Jehofa, o si da orun ati aye, ko ni pin ogo re pelu enikeni. Enikeni tabi Olorun miran ti oo ba npin ninu ogo re ni ki a ko sile. Gbogbo ola ati ogo ni ki a fi fun Olorun nikan ni gbogbo akoko.
ADURA
Olorun Olufe jowo je ki emi maa doju ko o nikansoso ninu ise ijosin mi. Mase je ki emi sin orisa, ma si se je ki emi pin ogo re pelu enikeni. Je ki gbogbo okan mi ro mo o ni gbogbo ojo aye mi, ki emi ba le je anfani ibukun re ni aye yi ati ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
