MA SE JE KI ILAKAKA FUN AGBARA GBA AYE RE KAN
Wolii Samueli jewo ara re bi adari ti o mo Olorun ni ile Isreali. O ti sin won daradara ko si baa lati ni ki awon eniyan ye ise ohun wo. O pe awon alagba Isreali ‘Woo emi niyi, jeri si mi niwaju Oluwa ati niwaju eni-ororo re, maalu ta ni mo gba ri? Tabi ketekete ta ni mo gba ri? Ta ni mo reje ri? Tani mo je ni iya ri? Tabi lowo tani emi gba owo abetele kan ri lati fi bo ara mi loju? Emi o si san an pada fun yin. Won si wipe iwo ko re wa je ri, bee ni iwo ko je ni ni iya ri, bee ni iwo ko gba nnkan lowo enikeni wa ri. O si wi fun won pe, Oluwa ni elerii si yin, ati eni ami-ororo re ni elerii lonii pee yin ko ri nnkan lowo mi. won si dahun wipe oun ni elerii. (Samueli kini 12:3-5).
EKO
Agbara maa ngun opolopo eniyan, won si ti si ipo won lo, oti wa di asa pe, agbara ndoti eniyan, gbogbo agbara a maa doti eniyan. Awon omo Olorun ko ni lati je ki agbara gun wa, a ko ni lati si agbara lo bi aba wa ni ipo giga kan. Ipokipo ti a le wa, a ni lati sin pelu irele. A ni lati bu ola fun Olorun pelu ise isin wa, ki a si se dede ni ojuse wa, ni afikun a ko ni lati je olokanjuwa pelu ipo wa. Ipokipo ti a ba wa, ki a se dede laisi imotara eni nikan. Olorun yi o bola fun Kristieni ti o ba fi ipo re ye Olorun si, yi o si fiya je enikeni ti o ba si ipo re lo.
ADURA
Olorun olufe jowo je kin je onirele, ki agbara mase gun mi, je kin lo ipo mi daradara kin mase ru ibinu re soke. Je kin fi iberu Olorun se ojuse mi gege bi asoju Jesu Kristi. Mo si gbadura fun awon alase, fun won ni okan ti o beru Olorun, ro won ni agbara lati le se idajo to ye. Mase je ki won doju ko imo tara eni nikan, sugbon ki won le sin ni ipokipo ti won ba wa, je ki o dara fun awon asejoba, ki Alafia si wa lori ile wa. Amin.
