OLORUN KI YIO KUNO LATI MU ILERI RE SI O SE
Dafidi Oba salaye ife nla re si Olorun, o si beere lowo eledaa lati b’ola fun ibura ijolotito. Dafidi wipe Oluwa ranti Dafidi ninu gbogbo iponju re, Eni ti o ti bura fun Oluwa, ti o si se ileri ife fun Alagbara Jakobu pe, nitooto, emi ki yio wo inu ago ile mi lo, beeni emi ki yio gun ori akete mi. Emi ki yio fi Oorun fun oju mi, tabi oogbe fun ipenpeju mi. Titi emi o fi ri aaye fun Oluwa, ibujoko fun Alagbara Jakobu. (Orin Dafidi 132:1-5).
EKO
Olorun mo iyi awon ti o bowo fun pelu otito. O ngboorun ijosin ti awon eniyan se bi ohun oloorun didun. Olorun yio yi isin otito awon eniyanti n josin fun un si ibukun. Yio bukun awon olootito omo re, won yio ni iriri ayo ati isegun. Nitori naa a ro gbogbo eniyan lati sin Olorun alaye, ki won si fi gbogbo aye won fun.
ADURA
Olorun olufe, je ki n yonda gbogbo aye mi fun o, ki emi si sin o ni otito. Je ki emi lee te o lorun pelu ohun gbogbo ti mo ni ka mi ye lati gba ibukun re ni aye yi ati ni orun pelu. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
