ABO OLORUN NBE LORI AWON OMO RE
IGBE AYE BIBELI
Dafidi pa Goliati o si gba oju rere lodo awon eniyan re, sugbon aseyori re fa owu jije oga re. Oba saulu beru, o si korira dafidi patapata. O de awon sile fun, o si nsa gbogbo ipa re lati paa. Sugbon olorun fi abo bo Dafidi kuro lowo saulu, ete ajinipa ni olorun so di asan. Bibeli salaye ero oba saulu si Dafidi pe emi buburu lati odo olorun wa si ba le saulu, o si jokoo ni ile re t’oun ti esin re lowo re’; Dafidi a si maa fi owo re korin lara duuru. Saulu ti nwa ona lati fi esin naa gun Dafidi mo ogiri sugbon oun si yera kuro niwaju Saulu, o si so esin naa wonu ogiri, Dafidi si sa, o si fi ara pamo ni oru naa.
(1samueli 19: 9-10).
EKO
Ota ododo le maa le omo olorun, sugbon yio pofo nikehin. Ota yio subu, sugbon olorun yio pa awon eni tire mo. Abo olorun yio wa daju lori awon omo re, yio si gba won ninu ewu kewu. Bi o ti wu ki ota ododo ri, agbara re kere/koto nkan, olorun ti nfi abo bo awon omo re ni agbara ti ko ni odiwon. Yio fi abo bo awon omo re kuro lowo ohun ija ota, yala eyi ti a le foju ri tabi eyi ti ko see foju ri. Jehofa yio lu awon ota bole niwaju eniyan re,ki won le ri titobi agbara re, ki won si yin oruko mimo re.
ADURA
Olorun olufe, mo bebe ki o bami segun gbogbo ota ti o nba mi jagun. Je ki awon ota mi subu sinu igbero ibi won. Fun won ni ayo fun ironupiwada, bi won ba ko, lu won bale ki o si so won di alailagbara. Nitemi, je ki nmaa goke sii pelu awo didan ninu ogo re ni oruko Jesu Kristi ni mo lbeere. Amin.
