B’OWO FUN IRANSE OLORUN
Obirin opo se itoju fun Wolii Elijah o si di eni ibukun lehin naa obirin opo ti ro tele pe, oun ati omode kunrin re yi o ku sinu osi sugbon itan igbe aye re yipada, logan ti o se iranlowo fun iranse Olorun. Bibeli rohin pe ‘Oun si dide, o si lo si Sarefati nigba ti o si de ibode ilu naa kiyesi, obirin opo kan unsa igi jo nibe, o si ke sii, o si wipe joo, bu omi die fun mi ninu ohun elo ki emi ki o le mu, bi o si ti unlo bu wa o ke sii, o si wipe joo, mu okele ounje die fun mi wa lowo re. Oun si wipe, bi Oluwa Olorun re ti wa, emi ko ni akara sugbon ikunwo iyefun ninu ikoko ati ororo die ninu kolobo, si kiyesii emi nsa igi meji jo ki emi ki o le wole lo, ki emi ki o le pese re fun mi ati fun omo mi ki awa le jee ki a si ku. Elijah si wi fun un pe ma beru, lo ki o si se gegebi o ti wi sugbon ki o tete se akara kekere kan fun mi ninu re naa, ki o si mu un fun mi wa leyin naa ki o se tire ati omo re. Nitori bayii ni Oluwa Olorun Isreali wi ikoko iyefun naa ki yoo sofo bee ni kolobo ororo naa ki yoo gbe, titi di ojo ti Oluwa yoo ro ojo si ori ile. O si lo o si se gege bi oro Elijah ati oun ati obirin naa ati ile re je ni ojo pupo, ikoko iyefun naa ko sofo bee ni kolobo ororo naa ko gbe, gege bi oro Oluwa ti o ti ipa Elijah so.
(Awon Oba Kini 17:10-16)
EKO
O je ohun ti o dara lati bukun awon iranse Olorun, awon ti o ba si se bee yi o ri ibukun gba lowo Olorun. Niwon igba ti oruko Olorun ni asopo pelu iranse re, o si maa unwa pelu won nigba gbogbo enikeni ti o ba bukun won yi o di eni ibukun pelu. Bakan naa enikeni ti o ba tako iranse Olorun, yi o jiya pelu, Jehofa yi o tako enikeni ti o ba tako iranse re.
ADURA
Olorun olufe mo mo pe o bukun mi bi mo ba bu ola fun awon iranse re, iwo o si fiya je mi bi mo ba yaju si won. Jowo ran mi lowo ki nle sora bi mo se huwa si awon iranse re, je ki unbola fun won, ki npese fun won, si ran mi lowo lati maa ranti won ninu adura mi, jowo bukun mi bi mo se ranti bukun awon iranse re ni aye, ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
