FI SI IMULO AGBARA TI JESU KRISTI FUN O
Jesu Kristi pase fun awon omo ehin re ki won maa wasu ihinrere, o si nti ise iranse won lehin pelu ise iyanu ati awon amin ti yio tele. O si pe awon omo ehin re mejila jo, o si fun won ni agbara ati ase lori awon emi esu gbogbo, ati lati wo arun san. O si ran won lo wasu ijoba olorun, ati lati mu awon olokunrun larada. O si wi fun won pe, e ma se mu nnkan lo fun ajo yin, opa, tabi apo tabi akara, tabi owo, bee ni ki eyin ki o ma si se ni awotele meji.
(Luku 9:1-3).
EKO
Jesu Kristi ni enikan soso ti a wo ni agbara ti a ko le dojuko lati de ati lati se itusile ni igbakugba. Olorun ti gbee woo, gbogbo agbara ti eda nilo ninu aseyori ti ale mimo. Bibeli fi idi eyi mule nitorina olorun pelu si ti gbe e ga gidigidi, o si ti fi oruko kan fun un ti o bori gbogbo oruko, pe ni oruko Jesu ni ki gbogbo eekun ki o maa wole, awon eni ti nbe ni orun,ati awon eni ti nbe ni ile, ati awon eni ti nbe ni isale ile ati pe ki gbogbo ahon ki o maa jewo pe, Jesu Kristi ni Oluwa fun ogo olorun baba. (Fillipi 2:9-11).
Sugbon Jesu ko je onimo tara eni nikan nipa ase re, o pinnu lati pin pelu awon atele re. Enikeni ti o ba jewo igbagbo re ninu Jesu Kristi yi o ni ase ati agbara lati bori ohunkohun ti o ba ndojuko ninu aye. Jesu wi fun awon omo ehin re” looto ni mo wi fun yin, ohunkohun ti eyin ba de ni aye, a o dee ni orun, ohun ti eyin ba si tu ni aye, a o tuu ni orun. (Matiu 18:18-19).
ADURA
Jesu Kristi olufe, iru omo olorun iyanu ni o ti o ni agbara ti o koja oye eniyan lati se ohun to ba wu o. Mo mo wipe awon omo ehin re ni iru agbara kan na, nitori pe mo je kristeni, atele re, mo so ara mi di alabapin ninu agbara re, mo si pinnu lati lo ni kikun fun ogo oruko olorun. Emi yio lo oruko/ase Jesu lati wasu, emi o si loo fun ise amin ati iyanu. Mo mo wipe emi ni mo je olori-ire julo ni agbaye nitori pe mo je omo lehin Jesu Kristi. Beni emi je asegun ninu igbagbo Oluwa mi, isegun mi yio si duro titi lai. Amin.
