IDANWO ONIGBAGBO
Jesu Kristi kilo fun awon omo ehin re wipe, igbe aye kristieni kii se kiki ‘Buredi ati bota’ kristieni yi o mu ki a gbojege igberaga wa, ki a ba le te Olorun lorun. Kristieni yi o mu ki a se ara wa fun awon igbadun kan, ki a fara da idanwo ki oruko Oluwa le di yinyin. Jesu ko awon omo ehin re o wipe ‘Won o yo yin kuro ninu sinagogu, ani akoko nbo ti enikeni ti o ba pa yin, yoo ro pe oun nse isin fun Olorun (Johanu 16:2) Jesu fi ye awon omo ehin re pe, ebun wa fun gbogbo ifara da won fun ijoba orun. Jesu wipe ‘E ma si je ki okan yin daru, e gba Olorun gbo, e gba mi gbo pelu. Ninu ile baba mi, opolopo ibugbe ni o wa, iba ma se bee emi iba ti so fun yin, nitori emi nlo pese aye sile fun yin, bi moba si lo pese aye sile fun yin, emi o tun pada wa, emi o si mu yin lo sodo emi funra mi, pe nibi ti emi gbe wa ki eyin le wa nibe pelu. Eyin simo ibi ti emi gbe nlo, e si mo ona naa
(Johanu 14:1-4)
EKO
Enikeni ti o ba jiya nitori Jesu Kristi yio gba ere ni orun, enikeni ti o ba fara da idanwo ati inunibini nitori tire yi o gba ade ogo, ti kii dibaje ni orun. Iponju yiowu ti kristieni doju ko looni ko ni wa titi lae lae, ko ni pe dopin, a o kaa si irubo nitori ihinrere. Olorun yi o san ere fun gbogbo ifarada ati igbojege ti a nse nitori ijoba re, o ye ki kristieni farada irora, ki o si duro sinsin ninu Jesu ki won baa le gba ebun nla lati odo Olorun. Jesu Kristi ti seleri wipe, oun ko ni fi onigbagbo sile ninu idanwo, yi o ro won ni agbara nipase Emi-Mimo ki won ba le ni isegun.
ADURA
Jesu Kristi olufe, jowo ran mi lowo, ki nduro sinsin ninu igbagbo ki a le de mi lade ni orun. Fun mi ni agbara nipase Emi-Mimo lati duro, ki emi si di eri re mu titi de opin, nigba ti opin bade je ki won ki mi ku abo ni orun, ki emi si ye fun ase mimo nla ti orun. Amin.
