ISE ASEPARI TI IGBALA
Jesu Kristi salaye idi ijiya ati iku re, iku re je ipa ona fun awon elese lati le ri idariji gba, ki won si ye fun orun rere. Jesu Kristi wipe ‘Bee ni o ti kowe re pe, ki Kristi ki o jiya ati ki o si jinde ni ojo keta kuro ninu oku, ati ki a waasu ironupiwada ati idariji ese ni oruko re ni orilede gbogbo, bere lati Jerusalemu lo, eyin si ni eleri nnkan wonyii. Si kiyesii mo ran ileri Baba mi si yin, sugbon e jokoo ni ilu Jerusalemu titi a o fi agbara wo yin lati oke orun wa.
(Luku 24:46-49)
EKO
Jesu Kristi ku fun awon elese lori igi agbelebu ‘O je asepe ise’ Kristi si iboju ati itumo iku ati ajinde re fun gbogbo eniyan. Ojuse re ti o sowon ni lati gba elese la ki o si mu won ni idapo pipe pada sodo eleda won. (Bakan naa, Kristi ro awon omo-ehin re ni agbara lati waasu ihinrere fun awon alaigbagbo) (Luku24:46-49) Onigbagbo ni atilehin orun, won si ni agbara Emi Mimo lati waasu ihinrere kakiri agbaye lai si iberu, looto Kristi jiya fun asepe igbala sugbon o so di ofe fun gbogbo eniyan. Ebun Emi Mimo si je ofe pelu enikeni ti o ba jewo Jesu Kristi ni Oluwa yi o je anfani yi.
ADURA
Jesu Kristi olufe emi ko le pidan pe nko loye ise iyanu eto igbala ti o se pari nipa iku ajinde re, o ti ku fun ese mi o si ti fun mi ni iye ayeraye. O si ti se ileri ebun Emi Mimo fun mi ki nba le waasu ihinrere bi o ti to, nitori naa mo yonda ara mi fun o looni mo gba o gege bi Oluwa ati olugbala mi, mo si beere fun imisi agbara Emi Mimo lati le waasu ihinrere daradara, jowo fun mi ni ore-ofe ki nle je omo re nitooto titi de opin. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
