OHUN IKORIRA NI ESE JE NI WAJU OLORUN
Dafidi se si Olorun, o si jiya ere ese re (Olorun seleri nipase woli Natani wipe Dafidi yio san fun ese agbere ti o da pelu Batseba ati pipa oko re (2samueli 12:7-12). Wahala be sile nile Dafidi. Awon re meji dese biba ara won lopo, ikan ninu won pa enikeji re. Ikan lara awon omo Dafidi pa arakunrin re, o si ni asepo ni gbangba pelu ale baba re. Omo kan na a le baba re kuro lori ite, o si gbiyanju lati paa. Dafidi so ijoba/ite re nu, o wa di alarinkiri ni oru-moju. Ogbeni Dafidi so ohun gbogbo to ni nu, o si ni iporuru okan. Die ninu ijiya Dafidi nitori ese re ni a ko si isale wonyi-
1. Awon omo Dafidi da ese biba ara won se po... oun si daa lohun wipe bee ko egbon mi, ma se temi, nitori pe ko to ki a se iru nkan be ni Israeli, itani iwo ma se nuwa were yi. Ati emi, nibo ni emi o gbe itiju mi wo? Iwo o si dabi okan ninu awon asiwere ni israeli. Nje nitori naa, emi be o, so fun oba, nitori pe oun ki yoo ko lati fi mi fun o. sugbon o ko lati gbo ohun re, o si fi agbara mu un, o si segun re, o si baa dapo. (2Samueli 13:12-14).
2. Omo Dafidi pa arakunrin re, Absalomu si fi ase fun awon iranse re pe ki eyin ki o maa kiyesi akoko ti oti-waini yi o mu okan Ammoni dun, emi o si wi fun yin pe, kolu Ammoni, ki e si paa, e ma beru, ki e se bi alagbara omo.Awon iranse Absalomu si se si Ammonigege bi Absalomu ti pase. Gbogbo awon omo oba si dide, olukuluku gun ibaka re, won si sa. (2Samueli 13:28-29).
3. Omo Dafidi dese agbere pelu ale re Ahitofeli si wi fun Absalomu pe, wole to awon obinrin baba re lo, awon ti o fi sile lati maa so ile, gbogbo Israeli yoo si gbo pe, iwo di eni irira si baba re, owo gbogbo awon ti o wa lodo re yoo si le. Won si te ago kan fun Absalomu ni ori orule, Absalomu si wole to awon obinrin baba re ni oju gbogbo Israeli. (2Samueli 16:21-22).
4. Omo Dafidi gba ijoba re, o si fe paa, enikan si wa ro fun Dafidi pe, okan awon okunrin israeli si si Absalomu. Dafidi si wi fun gbogbo iranse re ti o wa lodo re ni Jerusalemu pe, e dide, e je ki a salo, nitori pe ko si eni ti yoo gba wa lowo Absalomu, e yara, ki a lo kuro ki oun ma baa yara le wa ba, ki o ma si mu ibi ba wa, ki o ma si fi oju ida pa ilu run. (2Samueli15:13-14).
EKO
Olorun korira ese, ohun buburu ni, o le mu ki omo Olorun jiya. Ese nmu ki Olorun ka abo re kuro lori eni ti o ba dese, o si nfun satani ni aye lati soro. Nitorina omo Olorun ni lati kiyesara, ki won ma se faye gba ese, nitori o ni ijiya ninu. Ireti wa fun elese ti o ba ronupiwada kuro ninu ese re. Olorun alaanu ati oludariji, yi o saanu fun enikeni ti o ba fi irele jewo, ti o si ronupiwada ese re.
ADURA
Olorun olufe, jowo dari ese mi jin mi ki emi mase se si o. Mase je ki emi se si o, ki satani ma baa raye wonu aye mi. Wo mi ni agbara nipase emi mimo lati le pa gbogbo ofin re mo, ki o ranmi lowo, ki nle fi otito sin o, ki emi le se aseyori ninu aye mi titi lae. Ni oruko Jesu ni mo beere. Amin.
