OLORUN NDAHUN ADURA
Absalomu gba ijoba Dafidi baba re, o si pinu lati paa. Alaini ireti yi di alarinkiri ni aginju, lai mo pato ohun to le se. Ni akoko idamu yi, Dafidi ke pe Olorun ninu adura. Bibeli wipe Dafidi si ngoke lo ni oke igi ororo, osi nsunkun bi oun ti ngoke lo, o si bo ori re, o nlo laini bata ni ese, gbogbo eniyan ti o wa lodo re, olukuluku okunrin si bo ori re, won si ngoke, won si nsunkun bi won ti ngoke lo
(2Samuel 15:30).
EKO
Awon omo Olorun ni lati to olorun lo ninu adura, nigba ti won ba wa ninu isoro. Ile aye kun fun ohun rere ati ohun buburu, nitorina kristeni ni lati gbadura lati le bori won. Niwon igba ti olorun feran awon eniyan re, yi o gbo adura won. Ko ni ko awon eniyan tire sile ni akoko wahala. Olorun yi o gbo igbe awon omo re, yi o si mu ki oju won maa dan, ninu wahala ti won le dojuko.
ADURA
Olorun olufe, jowo ko mi lati le maa gbadura si o ni akoko isoro. Bi mo ba gbadura, jowo gbo igbe mi. Dahun adura mi, ki o si gbo ebe okan mi. Je ki n maa gbe ninu ayo, ifokanbale, ola titi gbogbo ojo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
