SISO ODODO ORO OLORUN ATI FIFI SINU ISE
Jesu Kristi yatọ si awon olukọ akoko re, o nkoni ni ipinlẹ otitọ ilana Olọrun ti o le mu ki Ọlugbọ fara ya. O ṣ̀e atun palẹ akori awọn Ọro o si fọ Ọro Olọrun si wẹwẹ ki awọn eniyan le mọ idi ti Olọrun ṣe nfẹ ki a jẹ mimọ.
Jesu kọ awọn eniyan, o si wipe
* Sure fun awọn ti nfi yin re (Luku 6:28)
* Si fi fun gbogbo eni ti o tọrọ lọdọ rẹ (Luku 6:30)
* Gẹgẹ bi ẹyin ti nfẹ ki eniyan ki o ṣe si yin, ki ẹyin si ṣe bẹ si wọn pẹlu (Luku 6:31)
* Ki ẹyin ki o fẹ awọn Ọta yin (Luku 6:35)
* Ẹ ma ṣe dani ni ẹjọ (Luku 6:37)
* Ẹ fun awọn eniyan ninu ifẹ pupọ (Luku 6:38)
ÈKỌ́
Kristieni ni lati ma tẹle ilana Jesu Kristi nipa kikọ awọn eniyan nipa awọn ohun ti ijọba Olọrun. Opọlọpọ otitọ ni ko ni tẹ ni lọrun, ti o si fa ipalara, sibẹ wọn ni lati gbọọ, ki wọn lẹ ni imọ amuyẹ ohun ti ijọba Olọrun, ki wọn si duro tii.
Awa Onigbagbọ ni lati ṣe ohun ti a nwasu, ki a le pe eniyan wa si igbe aye iwa mimọ. Sisọrọ nipa otitọ ijọba Olọrun ko gbudọ duro lori ijolootọ enikeni. Boya Kristieni sii ntiraka lori ofin Olọrun lọna kan ninu aye rẹ, O ni lati ri daju pe O nwasu otitọ Ọrọ Olọrun ni gbogbo igba, laise adalu tabi ki o yẹpẹrẹ Ọrọ Olọrun. Otitọ Olọrun ko yi pada, nitorina Onigbagbọ ni lati ma wasu re ni gbogbo igba. A ni lati kẹkọ lara Jesu ti gbogbo iwasu rẹ duro lori iwa mimọ, ti o jẹ amuyẹ fun Ẹnikeni ti o ba fẹ wọ ijọba Ọrun gẹgẹ bi Jesu ṣe sọ ‘Sugbọn ẹ tete maa wa ijọba Olọrun na, ati ododo rẹ, gbogbo nnkan wonyi ni a o fi kun fun yin. (Matiu 6:33)
Fun afikun, ki Kristieni to le kun oju iwọn ni iwasu ihin rere, o ni lati kun fun agbara Ẹmi Mimọ. Bi ẹmi mimo ko ba gbakoso tabi maa dari ko ṣe ṣe fun Ẹnikeni lati tẹ Olọrun lọrun. Emi mimọ yi o ran wa lọwọ lati le fẹ Olọrun ati awọn aradugbo alabagbe wa. Yi o si ran wa lọwọ lati le gbe pẹlu apẹrẹ wiwasu Ọrọ Olọrun ti ko ni abula.
ADURA
Jesu Kristi Jọwọ ran mi lọwọ lati jẹ olotitọ Kristieni ti mo ma fi gbe igbe aye ni ibamu pẹlu Ọro Olọrun. Ro mi ni agbara Ẹmi Mimo ki nle gbe igbe aye iwa mimọ niwaju rẹ. Je ki Ẹmi Mimọ rẹ kọ mi ‘Lati sọrọ to tọ, rin irin to tọ lati rin’ ni ireti jijere ijọba rẹ. Nigba ti ire ije mi ba pari, jọwọ ka mi yẹ ni ijọba ayeraye ki nlayọ niwaju rẹ laelae. Ni Orukọ Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
