WIWASU IHINRERE NIGBA TO WO ATI NI IGBA TI KO WO
Anderu ati ore re gbo ti Johanu njeri pe Jesu ni Kristi ti Olorun ran lati gba aye la, lesekese won tele Kristi lati di omo ehin re. Anderu sipe arakunrin re Simoni Peteru lati waba Jesu, Bibeli wipe ‘Okan ninu awon meji ti o gbo oro Johanu ti o si to Jesu leyin ni Anderu, arakunrin Simoni Peteru. Oun tete ri Simoni arakunrin oun funra re, o siwi fun un pe. Awa ti ri Messia, itumo eyi tii je Kristi, o si mu u wa sodo Jesu, Jesu si woo o wipe iwo ni Simoni omo Jona. Kefa ni a o ma ape o, itumo eyi ti je Peteru
(Johanu 1:40-42) ni ojo keji, Jesu ri Filipi o si so di omo ehin re, Filipi yi pada lati pe Natanieli lati dara po mo oga re titun. Iwe ipe na ntesiwaju opolopo eniyan ndara po mo Jesu lati di omo ehin re, bi awon eniyan se nbola fun ipe Jesu bee ni won ndi omo Olorun. Bi ijoba Olorun se nkun sii nipase iwe ipe Jesu, ijoba Satani ndiku bakan naa, iwe ipe naa si wa titi di oni.
EKO
Ohun ti o dara ni lati waasu ihinrere Jesu fun gbogbo eniyan, gbogbo eniyan le ma gba ipe wa, oko igbala le ma saiko gbogbo eniyan nigba kan naa sugbon yi o ma tesiwaju. Bi opo iwe ipe ti a ba nfi sowo si awon eniyan, beni anfani lati ri opo eniyan wa si ijoba orun, nitori na onigbagbo nilati maa waasu ihinrere Kristi fun gbogbo eniyan lai yo enikeni sile. A ko ni lati je ki okan wa poruru bi a ko ri eso lesekese, a le ma ri abayo ise wa ni aye sugbon won han ni orun. Opolopo le gbo ohinrere loni, ki won si di eni igbala ni ojo iwaju, ko si kristieni to ni lati duro de akoko ti o ba wun ki o to waasu ihinrere, a ko si ni lati ma duro de enikeni ki a to sise Olorun. Gbogbo kristieni ni lati ba awon alaigbagbo ni gbolohun ti o le sina okan won si ihinrere, a ko nilo ibi ti o teju ki a to waasu ihinrere, ki a gbiyanju lati ba okan kan pade nigba kan. A ni awon ore, aladugbo, akeko bi tiwa, alabasise ti a le to won lo pelu ihinrere, ko si awawi fun aile waasu ihinrere. Olorun yi o bukun awon omo re ti o ba gboran sugbon yi o fajuro si awon ti o ba kuna lati nawo igbala si awon eniyan gbogbo.
ADURA
Jesu Kristi mo setan lati waasu ihinrere, emi ko ni sun akoko siwaju mo. Mo ti pinu bayi ju ti atehinwa lo, emi yi o waasu ihinrere fun awon ore mi, ebi mi, aladugbo mi, akeko bi temi, alabasise. Emi yi o lo gbogbo akoko ti mo ba ni lati maa waasu ihinrere, mo beere ki o fun mi ni ore-ofe ati ohun ti mo ni ki nle je olotito ati afurugbin omo. Ro mi ni agbara Emi-Mimo ki nle se aseyori ninu ijoba re titi igbe aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
