AKO GBODO TELE IMORAN BUBURU
Rehoboamu tele imoran ti ko dara o si padanu ju abo ijoba ti o jogun lati odo baba re Solomoni, Rehoboamu ko imoran awon agbalagba sugbon o tele imoran awon odo ti won sii lona.
Bibeli wipe
"‘Rehoboamu si lo si Sekemu nitori gbogbo Isreali ni o wa si Sekemu lati fii je oba, o si se nigba ti Jeroboamu omo Nebati ti o wa ni Egipti sibe gbo, nitori ti o ti sa kuro niwaju Solomoni oba, Jeroboamu si jokoo ni Egipti.
Won si ranse pee ati Jeroboamu ati gbogbo ijo Isreali wa, won si so fun Rehoboamu wipe. Baba re so ajaga wa di wuwo unje nitori naa se ki isin baba re ti o le, ati ajaga re ti o wuwo ti o fi si wa ni orun ki o fere die, awa o si sin o. o si wi fun won pe e lo na titi di ijo meta, nigba naa ni ki e pada to mi wa, awon eniyan naa si lo.
Rehoboamu oba si ba awon agbaagba tii ma duro niwaju Solomoni baba re, nigba ti o wa laaye gbimo wipe, imoran ki ni eyin da ki emi ki o le da awon eniyan yii lohun? Won si wi fun pe, bi iwo o ba je iranse fun awon eniyan yii loni, ti iwo o si sin won, ti iwo o si dawon lohun, ati ti iwo o soro rere fun won, won o se iranse re titi lae. Sugbon o ko imoran awon agbaagba ti won baa da, o si ba awon ipeere ti won dagba pelu re ti won si duro niwaju re gbimo, o si wi fun won pe imoran kini eyin da ki awa ki o le da awon eniyan lohun, ti won ba mi so wipe se ki ajaga ti baba re fi si wa lorun ki o fuye die? Awon ipeere ti o dagba pelu re wi fun pe, bayii ni ki iwo ki o wi fun awon eniyan yii, ti won ba o so wipe baba re mu ki ajaga wa di wuwo sugbon iwo mu ki o fuye die fun wa, bayii ni ki iwo ki o so fun won, omo ika mi yoo nipon ju egbe baba mi lo.
Nje nisinsinyi, baba mi ti gbe ajaga wuwo ka yin, emi o fi kun ajaga yin, baba mi ti fi pasan na yin sugbon emi o fi akekee na yin. Bee ni Jeroboamu ni ijo keta gege bi oba ti da wipe, e pada to mi wa ni ijo keta , oba si da awon eniyan ni ohun ako, o si ko imoran awon agbaagba ti won ba da. O si so fun won gege bi imoran awon ipeere wipe, baba mi mu ki ajaga yin ki o wuwo emi o si bu kun ajaga yin, baba mi fi pasan na yin sugbon akekee ni emi o fi na yin. Oba ko si fi eti si ti awon eniyan naa nitori ti oro naa lati owo Oluwa wa ni, ki o le mu oro re se ti Oluwa ti owo Ahijah ara Silo so fun Jeroboamu omo Nebati.
Bee ni nigba ti gbogbo Isreali rii pe oba ko feti si ti won, awon eniyan naa da oba ni ohun wipe ipin kini awa ni ninu Dafidi? Bee ni awa ko ni ini ninu omo Jese, Isreali e pada si ago yin, unje maa bojuto ile re, Dafidi bee ni Isreali pada sinu ago won. Sugbon awon omo Isreali ti ngbe inu ilu Juda wonni Rehoboamu joba lori wa.
(Awon Oba Kini 12:1-17)
EKO
Awa omo Olorun ni lati kiyesara pelu adura nipa imoran ti a ba ri gba, ki ama baa si ese gbe ki a si se ohun ti ko dara, kristieni ko nilati tele imoran kan lai yee wo daradara ki o si gbadura. O ye ki a mo wipe kii se gbogbo imoran ni o ni ireti to dara, opo imoran ni o wa lati okan imora eni nikan won si wa lati bi olugba imoran subu. Omo Olorun ki o mase gba imoran lowo alaigbagbo nitori pe o lewu pupo, won le gbe won subu. Kristieni ni lati gba imoran lowo kristieni egbe won, ni Pataki kristieni ti o ba fe imoran ki o gbadura lati gba ebun Emi-Mimo, nitori oun ni olugbani ni imoran to ga ju lo.
ADURA
Olorun olufe jowo dari igbese mi ki emi mase wa imoran lo sodo awon alaigbagbo, ran mi lowo lati le to awon agbani ni imoran ti yi o dari mi lati gbe igbese to dara. Ran mi lowo kin le gbadura kinto mu imoran ti mo rigba lo sinu ise, mase je kin sare si idajo kin wa kabamo nikehin. Yala je ki Emi-Mimo gba mi ni imoran itunu, ro mi ni agbara ki nle gbe igbese ti yi o se mi ni anfani. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
