KRISTENI GBODO KEDE IHINRERE
Opo ninu kristieni igba ni ni won ko sinu awon asa tio ro pe krisetieni je esin awon Juu nikan, sugbon Peteru fi ye won wipe ko ri bee nipa sisalaye iriri re pelu kristieni ti kii se Juu. (Ti opolopo kasi alaigbagbo tabi keferi) bibeli fi ye wape ‘Awon aposteli ati awon arakunrin ti o wa ni Judea si gbo pe awon keferi pelu ti gba oro Olorun, nigba ti Peteru si goke wa si Jerusalemu awon ti ikola nbaa so, wipe iwo wole to awon eniyan alaikola lo o si ba won jeun
(Awon Aposteli 11:1-3) Peteru si da won lohun wipe ‘Nje bi Olorun si ti fi iru ebun kan naa fun won ti o ti fifun awa pelu nigba ti a gba Jesu Kristi Oluwa gbo, ta ni emi ti emi o fi le de Olorun ni ona. Nigba ti won si gbo nnkan wonyi won si pa enu won mo, won si yin Olorun logo wipe, nje Olorun fi ironupiwada si iye fun awon keferi pelu. (Awon Aposteli 11:17-18)
EKO
Enikeni yala kristieni tabi bee ko ti o yapa ti o nse idena fun elomiran lati je kristieni, o nse ilodi si ife Olorun. Emi Olorin ti nbe ninu onigbagbo kii pinya, Jesu Kristi jiya o si ku fun gbogbo eniyan, ko si onigbagbo kristieni ti o le maa se idena titan kale ihinrere. Ojuse kristieni kookan ni ki o ma kede ihinrere Jesu Kristi fun gbogbo eniyan, gbogbo kristieni ni lati sa gbogbo ipa lati waasu ihinrere fun gbogbo eya, ahon, orile-ede, asa, ipinle gbogbo. Ko si odiwon Olorun yi o bukun enikeni ti o ba koja agbegbe re lati tan ihin rere kale.
ADURA
Jesu Kristi olufe, jowo se mi ni asoju re nitooto ni aye, fi ran mi lowo lati le waasu ihinrere fun awon eniyan. Mase mi ni oludena wiwasu ihinrere sugbon ran mi lowo lati tan ina ihinrere siwaju sii, mo si gbadura fun awon iranse ihinrere ni gbogbo aye jowo kun won pelu ifami ororo ki o si wo won ni agbara. Fun won ni ore-ofe ki won le se ipin fun ihinrere, ki won ko awon eniyan wo inu ijoba re, je ki o segbe gbogbo agbara ti o ba ntako ihinrere. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
