AWON IJA WA KO N SE TI ARA
Jesu Kristi lo akoko lati so fun awon omo ehin re nipa ewu ti o wa niwaju won, O si kilo fun won lati gbaradi. Sugbon awon omo ehin re ko ni oye, won ko si mura sile bo ti ye. Eyi ti won iba ma gbawe pelu adura si Olorun fun idanwo ti o wa niwaju won, nse ni awon omo eyin nba ra won ja, faga gbaga larin ara won. Jesu kilo fun won (‘E je ki oro wonyi ki o wo yin ni eti, nitori a o fi omo-eniyan le awon eniyan sugbon oro na ko ye won, o sis u won ni oju, bee ni won ko si mo on eru si nba won lati beere idi oro naa. (LUKU 9:44-45) eyi ti won iba bere adura lesekese. Bibeli wipe (iyan kan si dide laarin won, ni ti eni ti yio se olori ninu won. Nigba ti Jesus mo ero okan won, o mu omode kan, o gbe joko lodo re O si wi fun won pe, enikeni ti o ba gba omode yi nitori oruko mi, o gba mi ati enikeni ti o ba gba mi, o gba eniti o ran mi, nitori eni ti o ba kere ju ninu gbogbo yin, oun naa ni yoo po (LUKU 9:46-48).
EKO
Kristieni ni lati ji giri ninu emi lati le bori idanwo igbagbo. A ko ni lati je ki awon afe aye gba wa lo, ki a wa gbagbe igbala iyebiye ti a ri gba nipase Jesu Kristi. Onigbagbo ni lati kun fun adura ninu ohun gbogbo, ki a si teti si idari emi-mimo, ki a le bori idanwo igbagboti ti o dide lati pe igbagbo wa nija. Ki a si maa ranti oro bibeli ti o wipe idanwo igbagbo ti o ba de ba wa gege bi ija ti emi, ki a ma si tumo won si ija ti ara. Gege bi a ti koo (Nitoripe kii se eje ati eran-ara ni awa nba jijakadi, sugbon awon ijoye, awon olola, awon alase ibi okunkun aye yii, ati emi buburu ni oju orun (EFESU 6:12).
ADURA
Jesu Kristi ololufe, jowo ran mi lowo ki n ja fafa ninu emi kin le sise labe idari emi mimo. Je kin ja fafa ninu gbigba awe pelu adura lati le bori gbogbo ipenija aye. Dari mi ki o si ko mi lati ni isegun lori aye, kinsi ye fun orun rere. Jowo ran mi lowo lati maa dagba sii ninu ore-ofe ati ifami ororo lati le maa te o lorun ni gbogbo igba. Ni oruko Jesu Kristi ni mo bere. Amin.
