IWA MIMO SE PATAKI NI IRIN WA PELU OLORUN
Arakunrin kan ti a npe ni Akani mu ki awon ebi re se si Olorun, iwa re si fa isubu ati iparun fun gbogbo orile ede. Isreali so wiwa labe imisi Olorun nu, won si jiya labe ota ti o kere si won. Olorun fi asiri eyi han Josua wipe dide eese ti iwo fi doju bole bayii? Isreali ti dese won si ti ba majemu mi je ti mo pa lase fun won. Ani won ti mu ninu ohun iyaasoto nni, won si jale, won si se agabagebe pelu, ani won si fi sinu eru won. Nitori na ni awon omo isreali ko se le duro niwaju awon ota won, won peyinda niwaju ota won, nitori ti won di eni ifibu, emi ki yoo wa pelu yin mo bi ko se pee eyin pa ohun iyasoto run kuro laarin yin (JOSUA 7:10-12).
EKO
Olorun feran iwa mimo. Awon omo re ni lati je mimo ki won to le je anfani abo re ti o daju. Ko si omo Olorun ti o wa ninu ese ti o le ma fe ki ore-ofe ma po si. ilana Olorun o rorun, bakan naa si ni yi o ni isepo fun enikeni ti o ba jewo ti o si ko iwa ese sile, sugbon yi o jina si enikeni ti o ban dese, bakan na Kristieni ko gbudo pete lati tan Olorun pelu iwa mimo ti ko pe. A ko le tan eleda, O nbere fun ojulowo iwa mimo. Olorun le ma se itewo gba wa, bi o tile je pe awo aso to dara, a nsan idamewa ati ore ninu ile ijosin wa, ayafi ki a gbe igbe aye iwa mimo. Olorun yio gba ore wa nigba ti a ba ye fun ese ti a si ngbe igbe aye iwa mimo.
ADURA
Olorun olufe, jowo ran mi lowo lati le gbe igbe aye iwa mimo, ki ibasepo mi pelu re ki o je alailabawon. Too isise mi kin mase subu sinu ese, ki Esu ma ba yan mi je. Je kin le ronupiwada ni tooto nigba ti mo ba da ese, ki emi siri idariji re gba. Jowo fun mi ni okan lati ma tele ofin re kin le se aseyori ni gbogbo iyoku ojo aye mi, kin le di eni itewogba ni ijoba re. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
