GEGE BI KRISTENI, ASE LATI SE AWO KO ISE KRISTI NBE NINU RE
Mose iranse olorun mu ise oludari re wa si opin nipa sisoro idagbere fun awon Israeli. O gba won niyanju, o si gbadura fun ise rere ni ile ti olorun ti se ileri fun won. Mose pe eya israeli kan kan, o si sure fun won ki reubeni ki o ye, ki o ma se ku, ki eniyan re ki o ma se mo niwon. Eyi si ni ti Judah, o si wipe, Oluwa, gbo ohun Judah, ki o si mu un to awon eniyan re wa; ki owo re ki o to fun un, ki iwo kio si se iranlọwo fun un lowo awon ota re.
Ati ni ti Lefi o wipe, ke ki Tunmimu ati Urimu re ki o wa pelu eni mimo re, eni ti iwo danwo ni massa, ati eni ti iwo ba ja ni omi meriba. Eni ti o wi ni ti baba re, ati ni ti iya re pe, emi ko ri i bee ni kosi jewo awon arakunrin, bee ni kosi mo awon omo re nitori ti won kiyesi oro re, won si pa majemu re mo. Won o maa ko jakobu ni idajo re, ati Israeli ni ofin re, won o maa mu turari wa siwaju re, ati odoodo ebo sisun sori pepe re.
Oluwa busi ohun-ini re, ki o si tewo gba ise owo re, lu egbe awon ti o dide sii, ati ti awon ti o korira re, ki won ki o ma se dede mo, Ati niti Benjamini, o wipe , olufe Oluwa yoo maa gbe ni alaafia lodo re, oun a maa bo o ni ojo gbogbo, oun a si maa gbe laarin ejika re. Ati ni ti Josefu o wipe, abukun Oluwa ni ile re, fun oun iyebiye orun, fun iri ati fun ibu ti o ba nisale ati fun eso iyebiye ti oorun mu wa, ati fun ohun iyebiye ti ndagba ni osoosu. Ati fun ohun Pataki oke nla igbaani, ati fun ohun iyebiye oke ayeraye, ati fun ohun iyebiye aye ati ekun re ati fun ife inurere eni ti o gbe inu igbe, je ki ibukun ki o wa si ori Josefu, ati si atari eni ti a yasoto, laarin awon arakunrin re Akobi ako maalu re, tire ni olanla, iwo re iwo agbanrere ni, oun ni yoo fi ti awon eniyan gbogbo, won a ni opin ile, awon si ni egbeegbarun-un Efraimu, awon si ni egbeegberun manase. Ati ni ti sebuluni, o wipe sebuluni, maa yo ni ijade re ati isakari, ninu ago re. Won ope awon eniyan naa sori oke, nibe niwon o ru ebo ododo, nitori pe won o ma mu ninu opolopo okun tabi ninu isura ti o pamo ninu iyanrin. Ati ni ti Gadi, o wipe, ibukun ni fun eniti o mu Gadi gbile o ba bi abo-kinniun fun ara re nitori pe nibe ni a fi ipin olofin pamo si, o si wa pelu awon olori eniyan naa, o si mu ododo Oluwa se, ati idajo re pelu Israeli. Ati ni ti Dani o wi pe omo kinniun ni Dani ti nfo lati basani wa. Ati ni ti Naftali, o wi pe, iwo Naftali, ti ojurere telorun, ti o si kun fun ibukun Oluwa gba iha iwo-oorun ati gusu. Ati ni ti Aseni o wi pe, ibukun omo ni ti Aseni, ki oun ki o si je itewogba fun awon arakunrin re, ki oun ki o si maa ri ese re sinu ororo. Bata re yoo jasi irin ati ide, ati bi ojo re, bee ni agbara re yoo ri. Ko si eni ti o da bi Olorun iwo Jesurumi, ti o gun orun fun iranlọwo re, ati ninu olanla re ni oju-orun. Olorun ayeraye ni ibugbe re ati nisale ni apa ayeraye wa, oun si ti ota kuro niwaju re, o si wipe maa parun. Isreali si jokoo ni Alafia, orison Jakobu nikan, ni ile oka ati oti-waini, pelupelu orun re nse iris ile. Alaafia ni fun iwo, Isreali tani o dabi re, iwo eniyan ti ati owo Oluwa gbala asa iranlọwo re, ati enki tii se ida olanla re. awon ota re yoo si terbia fun o, iwo o si maa te ibi giga won mole. (Deuteronomi 33:6-29).
EKO
Ohun ti o se Pataki ni ki eniyan ni ibasepo pelu Oluwa ki a si fi isododo sin, eni ti o ba se eyi yi o ri opolopo anfani ti yio si tun san de ori awon omo-omo re. Bi o ti nsele si gbogbo eniyan, omo Olorun le doju ko iji aye, Olorun olotito ko ni je ki ipenija ki o bori wa. Jehofa yi o ran awon omo re lati bori gbogbo ipenija. Ko si ohunkohun ti o le se idena ipinnu Olorun fun awon omo re, ninu ohunkohun to le de (Boya o tewon lorun, tabi ko tewon lorun) yi o fowo sowopo lati mu ife Olorun se. Nitorina gbogbo eni ti nsin Olorun ki o tesiwaju nitori opolopo anfani to wa niwaju. Awon ti ko ti pinnu lati ma sin Olorun, ki won se ipinu rere iyipada lati sin Olọrun, nitori ko si adanu ninu si sin olorun, yala opolopo anfani nibe nipa si sin olorun.
ADURA
Olorun olufe o ye mi pe o ni eto fun awon to ba nsin o. O ko ni jawon kule ni ojo isoro, sugbon o pese fun aini won. Nitorina o se oluse lori awon omo re titi ife re yio fi se laye won. Mo bura pe emi o bere lati ma sin o lati oni lo. Emi yi o fi gbogbo agbara mi sin o titi di ojo iku. Fun mi ni oore ofe lati le di ileri mi mu. Ati pelu, e ran igbagbo mi lowo ni gbogbo akoko, ki nba le je anfani ni gbogbo aye mi. Je ki oju mi ki oma dan, ati eri didara re mase kuro lenu mi lati akoko yi lo ati titi lailai, Ni oruko jesu ni mo beere. Amin.
