O NILO IGBAGBO TI O YE KORO
Obinrin kan ti o se aisan fun odun mejila pinnu lati gba iwosan, o si rii gba. O pinnu lati ru ofin awon ara juu, o fowo to iseti aso jesu Kristi lati gba iwosan re. Logan ni o ri iwosan nigbati o gbe igbese igbagbo. Bibeli wipe o si se, nigbati jesu pada lo,awon eniyan tewogba a; nitori ti gbogbo won ti nreti re. Si kiyesi, Okunrin kan ti a npe ni Jauru, okan ninu awon olori sinagogu, o wa, o si wole leeba ese Jesu, o bee pe ki o ma sai wa si ile oun. Nitori o ni omobinrin kan soso, omo iwon odun mejila, o n ku lo. Bi o si ti nlo, awon eniyan nha e ni aye. Obinrin kan tio si ni isun eje lati igba odun mejila ti o na ohun gbogbo ti o ni fun awon onisegun, bee ni a ko le mu larada lati owo enikan wa. O wa leyin re, o fi owo to iseti aso re, logan ni isun eje re si gbe (Luku 8:40-44).
EKO
Ailasan ti o ba gbagbo ninu olorun fu iwosan yi o ri iwosan iyanu gba. Gbogbo Onigbagbo le je alategba iwosan re bi o ba ni igbagbo ninu olorun.. Igbagbo riri iwosan, itusile ati anfani miran nfe ki a gbe igbese. Omo olorun ye ki o le gba iwosan re ninu aye ti emi ki o si ri gba lesekese. Nigba ti olorun ba ri igbiyanju eda, olorun yi o fun eniyan ni ohun ti o ba nbeere. Ni oro kan, igbagbo aye yi o je ki omo olorun bori ohun kohun ti o le doju ko aye re.
ADURA
Olorun olufe, jowo ko mi bi mo se le mu si ise igbagbo aye, ran mi lowo ki nle fi igbagbo si sise,je kin fi igbagbo mi si ise ki o le yori si ibukun mi. Wayi, mo fi si ise igbagbo mi lori gbogbo aniyan aye mi. Mo palase loruko Jesu Kristi ki gbogbo aisan ko pare. Mo de, mo si pase ki o jade, gbogbo emi aisan, iporuru okan, osi ninu aye mi. Mo kede imularada, idande mi ni agbara ti nbe ni oruko Jesu Kristi. Lati akoko yi lo, nko si ni abe ijegaba satani, emi je asegun, emi o si ma segun nipase oruko Jesu Kristi Oluwa mi. Amin.
