IGBE AYE TO YE KOROO
Olorun fi esun kan awon omo Isreali nipa aiduro dede won (agabagebe) o wipe Isreali omo re je igbadun, o sanra nipa igbadun, o si koo sile lehin eyi. Isreali je anfani Olorun, won si tun pada sinu iborisa won, eleda seleri lati fiya je Isreali fun ohun ti won se yi, Olorun wipe nigba ti Efraimu soro, iwariri ni, o gbe ara re ga ni Isreali sugbon nigba ti o se ninu Baali o ku. Nisisinyi won si da ese kun ese won, won si ti fi fadaka won se ere dida fun ara won ati orisa imo won, ise onisona ni gbogbo re won wi ni ti won pe, je ki awon eniyan ti unrubo fi enu ko awon maaluu ni enu. Nitori naa awon o se da bi ikuuku owuro ati bi iri owuro ti unkoja lo, bi iyangbo ti a ti owo iji gba kuro ninu ile ipaka, ati bi eefin ti ijade kuro ninu ile eefin. Sugbon emi ni Oluwa Olorun re lati ile Egipti wa, iwo ki yoo si mo Olorun kan bikose emi, nitori kosi olugbala kan leyin emi. Emi ti mo o ni aginju ni ile ti o pongbe, gegebi a ti bo won bee ni won yo won si gbe okan won ga nitorina ni won si gbagbe mi, nitori naa ni emi o se da bi kiniun si won, emi o si maa so won bi ekun ni eba ona, emi o pade won bi beari ti a gba ni omo. Emi o si fa awon okan won ya, nibe ni emi o si je won run bi kiniun, eranko igbe ni yoo fa won ya.
(Hosia 13:1-8)
EKO
Awon omo Olorun ko ni lati se aisododo pelu Olorun. Ko to ki a je anfani Olorun tan ki a wa ko ehin sii, a ko ni lati tan Olorun je bikose ki a fi okan otito sin in. ki a ni inu kan pelu re, ki a fi imore han ninu ise isin wa, ki a mase je alaimore lehin ti a ba ti je ninu anfani re. Olorun unfe ki a ko ese sile ki a si tele ona otito re, ki a baa le di eni ibukun. Olorun unfe ki gbogbo eniyan gbagbo ninu Jesu Kristi gege bi olugbala araye ti o ni kokoro ti o lo si orun, enikeni ti o ba gboran si ofin Olorun, ti o si sin in yi o di alabukun fun.
ADURA
Olorun olufe, mo fe gbe igbe aye ti o ye kooro. Ran mi lowo lati wa ni isokan pelu re ni gbogbo isesi mi, je kin in je pipe ati olotito niwaju re ni gbogbo igba, ro mi ni agbara lati le maa dupe didara re ninu aye mi, si je kin lo eyi ti o dara ju ninu aye mi lati maa yin oruko mimo re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
