AGBODO SO ESO
Ilepa Paulu ni lati waasu ihinrere Jesu Kristi jake jado agbaye, aniyan re ni ki o le de awon ibi ti won koi tii gbo nipa ihinrere. Paulu so nipa asotele Isaiah (Isaiah 52:15) ti o wipe ‘Sugbon gege bi a ti koo pe awon eni ti a ko ti nsoro re fun, won o rii, ati awon ti ko tii gbo, oye yoo ye won (Romu 15:21).
EKO
Paulu je atele Jesu Kristi tooto ti o nlo kaakiri lati maa rohin nipa ti oga re. Paulu la opolopo ewu awon ajinipa, ni ojojumo ni o nfi emi re wewu lowo awon olokan lile ti o nwaasu fun, pelu gbogbo ipenija wonyi Paulu iranse Olorun ko rewesi lati waasu ihinrere. Airewesi re si mu ere wa nikehin, nipa iwasu ti o peye ti Paulu awon ara Asia, Hellene ati awon ara Romu ni ihinrere de odo won. Akosile Paulu si awon alaigbagbo di koko ninu Bibeli, niwon ti Paulu je eniyan ti o je kristieni bi tiwa, o ye ki a se giri ki a sise nla fun ijoba Olorun, a ni lati mu okan le lati waasu ihinrere Jesu Kristi fun awon to yi wa ka ati kakiri agbaye. Gbogbo kristieni lai yo enikeni sile nilati mo pe, ojuse wa ni lati waasu ihinrere Jesu Kristi kakiri gbogbo aye, Olorun yi o si be ise wa wo, yi o fun wa ni ere bi ise igboran wa se to si ofin re-wiwasu ihinrere.
ADURA
Olorun olufe emi ko fe je omo ti ko ni eso, sugbon mo fe je omo eleso ninu ijoba re, je ki wiwaasu ihinrere re ni aye ju ise kristieni ti o ba ku lo. Fun mi ni agbara lati maa rohin Jesu Kristi fun awon aladugbo mi, awon ore mi ati awon ebi mi, je kin je oluranlowo fun ijo mi ati awon ijo miran, ki itankale ihinrere Jesu Kristi le de awon orile ede to o jina. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
