OLORUN KORIRA ESE
Olorun ran awon omo Isreali leti pe ijiya nbe fun ese ti won ba da ayafi ki won ronupiwada. Eleda se ileri lati yi ibi kuro lori awon omo re bi won ba yi okan pada, ki won ma lepa ododo. Olorun so wipe ‘E furugbin fun ara yin ni ododo, e ka ni aanu, e tu ile yin ti a ko ro nitori o to akoko lati wa Oluwa, titi yi o fi de ti yoo si fi rojo ododo si yin.
(Hosea 10:12)
EKO
Ifijiya Olorun wa fun eniyan fun iwa ese won, osuwon ododo re yi o fun awon ti unlepa ati sin ni ododo ni ere ijolooto ninu ise isin won. Olorun yi o lepa awon onise buburu ati ika eniyan yi o ba won, yi o si rojo ibinu re le won lori. Eleda unfe ki gbogbo eniyan ronupiwada kuro ninu iwa ika won ki o ba le bukun won pelu ailonka Alafia ati ibukun.
ADURA
Olorun olufe mo mo pe o ti ni osuwon lati bukun olododo eniyan ati lati fiya je awon ika eniyan, nitorina mo fe je olododo omo re ki emi le di alabukun fun. Jowo fun mi ni agbara lati ronupiwada ese mi, ki nsi fi otito sin o ki unle je anfani ibukun re ni aye yi ati orun pelu. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
